Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 2:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó mú ìparun bá ibimímọ́,ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú Síónì gbàgbéọjọ́ àṣè àti ọ̀ṣẹ̀ tí ó yàn;nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó runọba àti olórí àlùfáà.

7. Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.Ó sì fi lé ọ̀ta lọ́wọ́àwọn odi ààfin rẹ̀;wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwagẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìpèjẹ tí a yàn.

8. Olúwa pinnu láti faògiri tí ó yí ọmọbìnrin Síónì ya.Ó gbé wọn sórí òṣùnwọ̀n,kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.Ó mú kí ilé-ìsọ́ àti odi rẹ̀ sọ̀fọ̀wọ́n ṣòfò papọ̀.

9. Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,kò sí òfin mọ́,àwọn wòlíì rẹ̀ kò ríìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.

10. Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónìjókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;wọ́n da eruku sí orí wọnwọ́n sì wọ aṣọ àkísà.Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jérúsálẹ́mùti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 2