Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 2:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.Ó ti sí ọ nípò láì láàánú,ó fún ọ̀tá ní ìsẹ́gun lórí rẹ,ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

18. Ọkàn àwọn ènìyànkígbe jáde sí Olúwa.Odi ọmọbìnrin Síónì,jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ ṣàn bí odòní ọ̀sán àti òru;má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,ojú rẹ fún ìsinmi.

19. Dìde, kígbe sókè ní àsálẹ́,bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀tú ọkàn rẹ̀ jáde bí ominíwájú Olúwa.Gbé ọwọ́ yín sókè sí inítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀tí ó ń kú lọ nítorí ebiní gbogbo oríta òpópó.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 2