Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 1:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,Júdà lọ sí àjòÓ tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ibi tí kò ti le sá àṣálà.

4. Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀,nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn.Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro,àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora,àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn,òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.

5. Aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

6. Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé.Àwọn ọmọ ọba kùnrin dàbí i ìgalàtí kò rí ewé tútù jẹ;nínú àárẹ̀ wọ́n sáréníwájú ẹni tí ó ń lé wọn.

7. Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ niJérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un.Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ówọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

8. Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ó sì ti di aláìmọ́.Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀;ó kérora fúnra rẹ̀,ó sì lọ kúrò.

9. Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;olùtùnú kò sì sí fún un.“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,nítorí àwọn ọ̀ta ti borí.”

10. Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ légbogbo ìní rẹ;o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣàtí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 1