Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 8:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Padà tọ Fáráò lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi.

2. Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọ lu gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ.

3. Odò Náílì yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gókè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ìbùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.

4. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

5. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kékèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Íjíbítí.’ ”

6. Ní ìgbà náà ni Árónì sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Éjíbítì, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀.

7. Ṣùgbọ́n àwọn onídan ilẹ̀ Éjíbítì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn. Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gun wá sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.

8. Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rúbọ sí Olúwa.”

Ka pipe ipin Ékísódù 8