Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 8:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Padà tọ Fáráò lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi.

2. Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọ lu gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ.

3. Odò Náílì yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gókè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ìbùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.

4. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

5. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kékèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Íjíbítí.’ ”

6. Ní ìgbà náà ni Árónì sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Éjíbítì, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀.

7. Ṣùgbọ́n àwọn onídan ilẹ̀ Éjíbítì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn. Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gun wá sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.

8. Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rúbọ sí Olúwa.”

9. Mósè sọ fún Fáráò pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Náílì nìkan.”

10. Fáráò wí pé, “Ni ọ̀lá.”Mósè sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa.

11. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò fi ìwọ àti àwọn ilé yín àti ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, wọn yóò sì wà nínú Náìlì nìkan.”

12. Lẹ́yìn tí Mósè àti Árónì tí kúrò ní ìwájú Fáráò, Mósè gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti ran sí Fáráò.

13. Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko.

14. Wọ́n sì kó wọn jọ ni okíti okíti gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.

15. Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Fáráò rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí.

16. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó sì ń ta ni)

17. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí.

Ka pipe ipin Ékísódù 8