Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 4:16-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

18. Mósè padà sí ọdọ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Íjíbítí láti wò bóyá wọ́n sì wà láàyè ṣíbẹ̀.”Jẹ́tirò sì dáhùn, ó wí pé, “Má a lọ ni àlàáfíà.”

19. Nísínsìnyìí, Olúwa ti sọ fún Mósè ni ilẹ̀ Mídíánì pé, “Má a padà lọ sí Éjíbítì, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.”

20. Mósè mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Éjíbítì. Ó sì mú ọ̀pa Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

21. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Éjíbítì rí i pé ìwọ se iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Fáráò. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì ṣé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.

22. Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Fáráò pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Ísírẹ́lì ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin,

23. mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ”

24. Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé-èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mósè, ó sì fẹ́ láti pa á.

25. Ṣùgbọ́n Ṣípórà mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó si fi awọ rẹ̀ kan ẹṣẹ̀ Mósè. Ṣípórà sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.”

26. Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí àkọlà abẹ́.

27. Olúwa sì sọ fún Árónì pé, “Lọ sínú ihà láti lọ pàdé Mósè.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mósè ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

28. Ní ìgbà náà ni Mósè sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti sọ fún un àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Fáráò.

29. Mósè àti Árónì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ.

30. Árónì sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mósè fún wọn

31. Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ amì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 4