Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:29-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30. “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fi hàn ọ́ lórí òkè.

31. “Ìwọ yóò si ṣe aṣọ ìgélé aláró àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ògbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tíí ṣe ọlọ́nà, pẹ̀lú ti àwọn kérúbu ni kí á ṣe é.

32. Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kaṣíà mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ìhò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.

33. Ṣo aṣọ títa náà sí ìṣàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ.

34. Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ.

35. Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fitílà sí ọ̀kánkán rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36. “Fún ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elésèé àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe.

Ka pipe ipin Ékísódù 26