Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26:14-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀.

15. “Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa.

16. Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀.

17. Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.

18. Ṣe ogún (20) pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà

19. Ṣe ogójì (40) ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.

20. Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó ṣíbẹ̀

21. àti ogójì (40) ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan.

22. Ṣe pákó mẹ́fà sí ni ìhà opin ìwọ̀ òòrùn àgọ́ náà,

23. kí o sì se pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn.

24. Ní igún méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bẹ́ẹ̀.

25. Bẹ́ẹ̀ ni pákó mẹ́jọ yóò wà, àti ihò itẹ̀bọ̀ mẹ́rìndínlógún (16) fàdákà yóò wà, méjì ní ìṣàlẹ̀ pákó kọ̀ọ̀kan.

26. “Bákan náà ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kaṣíà márùn ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà,

27. Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà.

28. Ọ̀pá ìdábùú àárin ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti òpin dé òpin pákó náà.

29. Bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30. “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fi hàn ọ́ lórí òkè.

31. “Ìwọ yóò si ṣe aṣọ ìgélé aláró àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ògbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tíí ṣe ọlọ́nà, pẹ̀lú ti àwọn kérúbu ni kí á ṣe é.

32. Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kaṣíà mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ìhò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.

Ka pipe ipin Ékísódù 26