Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 22:13-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà.

14. “Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ aládúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni ín kò sí nítòòsí. O gbọdọ̀ san án padà.

15. Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé ó háyà ẹranko náà ni, kò ní láti san ẹ̀san padà, owó tí ó fi háyà ẹranko yìí ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú.

16. “Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúndíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.

17. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀, fún fí fẹ́ ẹ ní wúndíá.

18. “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láàyè.

19. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lopọ̀ ní a ó pa.

20. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá rúbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.

21. “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò ni ilẹ̀ Éjíbítì rí.

22. “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ.

23. Bí ìwọ bá se bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.

24. Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba.

25. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrin yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

26. Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí òòrùn tó ó wọ̀,

27. Nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sími, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi.

28. “Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run tàbí sẹ́ èpè lé orí ìjòyé àwọn ènìyàn rẹ.

29. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ire oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ.“Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi.

Ka pipe ipin Ékísódù 22