Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 12:9-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà.

10. Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ̀ kejì, bí ó bá sẹ́ kú di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná.

11. Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.

12. “Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àtènìyàn, àtẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Éjíbítì. Èmi ni Olúwa.”

13. Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ àmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò ré e yín kọjá. Ìyọnu kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Éjíbítì láti pa wọ́n run.

14. “Èyí ni ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò máa ṣe ìrántí láàrin àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe àjọ ọdún rẹ fún Olúwa; ìlànà tí yóò wà títí ayé.

15. Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Ísírẹ́lì.

16. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ pe àpèjọ mímọ́, kí ẹ sì pe àpèjọ mímọ́ mìíràn ni ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe se iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, yàtọ̀ fún pípèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn láti jẹ: Èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.

17. “Ẹ ṣe àpèjẹ àkàrà aláìwú, nítorí ọjọ́ yìí ni mo mú un yín jáde ni Éjíbítì. Ẹ ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí yóò wà títí ayé ní àwọn ìran tí ń bọ̀.

18. Búrẹ́dì ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún osù àkọ́kọ́.

19. Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọ́dọ́ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárin àwùjọ Ísírẹ́lì, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà.

20. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.”

21. Ní ìgbà náà ni Mósè pé gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́ àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sí pa ẹran àjọ ìrékọjá Olúwa.

22. Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀.

23. Ní ìgbà tí Olúwa bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Éjíbítì láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé yín, yóò sì re ẹnu ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láàyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín.

24. “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrin yín àti àwọn ìran yín.

25. Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí Olúwa yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsí àjọ yìí.

26. Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’

27. Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé e wa ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Éjíbítì. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Éjíbítì.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn.

Ka pipe ipin Ékísódù 12