Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 12:32-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi.”

33. Àwọn ara Éjíbítì ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn. Wọ́n wí pé, “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú!”

34. Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun pípò kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì.

35. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ fún wọn. Wọ́n sì béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú.

36. Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Éjíbítì.

37. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn láti Rámẹ́sẹ́sì lọ sí Sukoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọ̀gbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

38. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù.

39. Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Éjíbítì wá ní wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú. Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn.

40. Iye ọdun ti àwọn ará Ísírẹ́lì gbé ní ilẹ̀ Éjíbítì jẹ́ irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).

41. Ní ọjọ́ ti irínwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430) pé gan an ni gbogbo ènìyàn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

42. Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní òru yìí ni gbogbo Ísírẹ́lì ní láti máa se àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀.

43. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá:“Àjòjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀.

44. Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà,

45. Ṣùgbọ́n àlejò àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 12