Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 5:21-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí aya aládúgbò rẹ, má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí ilé tàbí ilẹ̀ alábágbé rẹ, sí ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí ohunkóhun tí í ṣe ti aládúgbò rẹ.”

22. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri: Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.

23. Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn alàgbà a yín tọ̀ mí wá.

24. Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárin iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láàyè lẹ́yìn tí Olúwa bá bá a sọ̀rọ̀.

25. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.

26. Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?

27. Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́ran.”

28. Ọlọ́run ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀ Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,

29. ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.

30. “Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn.

31. Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àsẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”

32. Torí èyí ẹ sọ́ra láti máa ṣe ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí sósì.

33. Ẹ rìn ní gbogbo ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ bá à le yè, kí ó sì dára fún un yín, kí ọjọ́ ọ yín bá à lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà.

Ka pipe ipin Deutarónómì 5