Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 8:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá, àti sí gúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó leè dojú kọọ́, kò sí ẹnìkan tí ó leè yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.

5. Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrin ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láì fi ara kan ilẹ̀.

6. Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, ó sì dojú kọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára.

7. Mo ríi tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojú kọ ọ́, Òbúkọ náà kàn-án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.

8. Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.

9. Lára ọ̀kan nínú un wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúsù, àti sí ìhà ìlà oòrun àti sí ilẹ̀ dídára.

10. Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,

11. ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, ó sì gba àyè ibi mímọ́ rẹ̀.

12. A fún-un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.

13. Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 8