Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 4:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.

4. Èmi Nebukadinéṣárì wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.

5. Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùṣùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.

6. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.

7. Nígbà tí àwọn onídán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún mi.

8. Ní ìkẹyìn Dáníẹ́lì wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú un rẹ̀.)

9. Mo wí pé, “Beliteṣásárì, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì sí àsírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.

10. Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrin ayé, igi náà ga gidigidi.

11. Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.

12. Ewé e rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ká rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

13. “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró ṣíwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 4