Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 3:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nebukadinéṣárì ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní agbègbè ìjọba Bábílónì.

2. Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.

3. Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadinésárì ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.

4. Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo:

5. Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”

7. Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinéṣárì gbé kalẹ̀.

8. Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará a Júdà.

9. Wọ́n sọ fún ọba Nebukadinṣárì pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.

10. Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà

11. àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó forí balẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.

12. Ṣùgbọ́n àwọn ará a Júdà kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agèégbè ìjọba Bábílónì: Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

13. Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.

14. Nebukadinéṣárì wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Sádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.

15. Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

16. Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadinéṣárì, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 3