Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 1:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Mo bẹ̀rù Olúwa mi, ẹni tí o ti pèṣè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí ì rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”

11. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Dáníẹ́lì, Hananiáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà pé,

12. Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ẹ̀fọ́ láti jẹ àti omi láti mu.

13. Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí.

14. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.

15. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ.

16. Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ẹ̀fọ́ dípò rẹ̀.

17. Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òyé nínú un gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Dáníẹ́lì sì ní òyé ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.

18. Ní òpín ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá ṣíwájú ọba Nebukadinésárì.

19. Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba.

20. Nínú un gbogbo ọ̀ràn, ọgbọ́n àti òyé tí ọba ń bèrè lọ́wọ́ ọ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọn tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.

21. Dáníẹ́lì sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kírúsì.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 1