Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 5:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Píláédì àti ÓríónìẸni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀Tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹẸni tí ó wọ́ omi òkun jọpọ̀Tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

9. Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódiTí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ aládé di ahoro

10. Ìwọ kórìíra ẹni tí ń ṣòdì ní ẹnu ibodèó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́

11. Ìwọ ń tẹ talákà mọ́lẹ̀o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọnNítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́léṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọnNítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn

12. Nítorí mo mọ iye àìṣedédé rẹmo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀o sì ń fi òtítọ́ du talákà ní ilé ẹjọ́

13. Àwọn ọlọgbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyíNítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.

14. Wá rere, má ṣe wá búburúkí ìwọ ba à le yèNígbà náà ni Olúwa alágbára yóò wà pẹ̀lú ù rẹ.Òun yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ bí ìwọ ṣe wí

15. Kòrìírà búburú kí o sì fẹ́ rereDúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́Bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbárayóò síjú àánú wo ọmọ Jósẹ́fù tó ṣẹ́kù

16. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run alágbára wí:“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónàigbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlúA ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sunkúnÀti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún

17. Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàràNítorí èmi yóò la àárin yín kọjá,”ni Olúwa wí.

18. Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́nítorí ọjọ́ Olúwakí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́

19. Yóò dàbí ọkùnrin tí ó sá láti ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.Tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu ẹkùnyóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọtí ó simi lé ògiri ilé rẹ̀tí ejò sì bù ú ṣán.

20. Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?Tí ó sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀

21. “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àṣè ẹ̀sìn in yínÈmi kò sì ní inú dídùn sí àpèjọ yín

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà wáÈmi kò ní tẹ́wọ́n gbà wọ́nBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.Èmi kò ní náání wọn.

Ka pipe ipin Ámósì 5