Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 59:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

3. Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi.Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀,ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

4. Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo;kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́;wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà

5. Wọn ń pa ẹyín pamọ́lẹ̀wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,àti nígbà tí a pa ọ̀kan, pamọ́lẹ̀ ni ó jáde.

6. Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdàkú sì kún ọwọ́ wọn.

7. Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 59