Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 58:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ǹjẹ́ èyí ha ni irú ààwẹ̀ tí mo yàn bí,ọjọ́ kanṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?Í haá ṣe kí ènìyàn tẹ orí i rẹ̀ ba bí i koríko láṣán ni bíàti ṣíṣùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ nìyí,ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

6. “Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodoàti láti tú gbogbo okùn àjàgà,láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?

7. Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń paàti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòsì tí ń rìn káàkirinígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòòhò, láti daṣọ bò ó,àti láti má ṣe lé àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran yín sẹ́yìn?

8. Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájúù rẹ,ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.

9. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.“Bí ẹ̀yin bá mú àjàgà aninilára kúrò,pẹ̀lú ìka àléébù nínà àti ọ̀rọ̀ ìṣáátá,

10. àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń patí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,àti òru yín yóò dàbí ọ̀ṣán-gangan.

11. Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;òun yóò tẹ́ gbogbo àìní ìn yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí òòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀yóò sì fún egungun rẹ lókun.Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáadáa,àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í tán.

12. Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ róa ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wóàti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú un rẹ̀.

13. “Bí ìwọ bá pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́-ìsinmi jẹ́,àti síse bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùnàti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọàti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbíkí o máa ṣọ̀rọ̀ òòrayè,

Ka pipe ipin Àìsáyà 58