Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 56:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àti àwọn àjèjì tí ó ṣo ara wọn mọ́ Olúwaláti sìn ín,láti fẹ́ orúkọ Olúwaàti láti foríbalẹ̀ fún ungbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

7. àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mièmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọnni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi;nítorí a ó máa pe ilé mi níilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè.”

8. Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé—ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Ísírẹ́lì jọ:“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lúu wọnyàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ.”

9. Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú un pápá,ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

10. Àwọn olùṣọ́ Ísírẹ́lì fọ́jú,gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,wọn kò lè gbó;wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.

11. Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;wọn kì í ní ànító.Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò ní òye;olúkúlùkù ń yà sọ́nà ara rẹ̀,ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.

12. “Wá,” ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, “fún mi ní ọtí wáìnì!Jẹ́ kí a mu ọtí bíà wa lámu yóọ̀la yóò sì dàbí òní,tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 56