Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 51:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Tẹ́tí sími, ẹ̀yin ènìyàn mi;gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè mi:Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè.

5. Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wásí àwọn orílẹ̀ èdè.Àwọn erékùṣù yóò wò míwọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.

6. Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,wo ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀;Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wùàwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.

7. “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun tótọ́,ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyàa yín:Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàntàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.

8. Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ;Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí Ẹ̀gbọ̀n òwú.Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”

9. Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbáraÌwọ apá Olúwa;dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.Ìwọ kọ́ lo ké Rékábù sí wẹ́wẹ́tí o sì fa ewèlè yẹn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?

10. Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi òkun bíàti àwọn omi inú ọ̀gbun,Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìṣàlẹ̀ òkuntó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?

11. Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ;ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn.Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọnìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran-ara,àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

Ka pipe ipin Àìsáyà 51