Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 49:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹyóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’

21. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?A fi èmi nìkan sílẹ̀,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22. Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí níyìí:“Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlàÈmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọnwọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrinní èjìká wọn.

23. Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ,àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mini a kì yóò jákulẹ̀.”

24. Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?

25. Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí níyìí:“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbékùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.

26. Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹẹran ara wọn;wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yóbí ẹnii mu wáìnì.Nígbà náà ni gbogbo ọmọnìyàn yóò mọ̀pé Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kanṣoṣo ti Jákọ́bù.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 49