Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 45:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;jẹ́ kí àwọ̀sánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbàgàdà,jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

9. “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrin àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,‘Òun kò ní ọwọ́?’

10. Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé‘Kí ni o bí?’tàbí sí ìyá rẹ̀,‘Kí ni ìwọ ti bí?’

11. “Ohun tí Olúwa wí nìyìíẸni Mímọ́ Ísírẹ́lì, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀:Nípa ohun tí ó ń bọ̀,ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

12. Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayétí ó sì da ọmọnìyàn sóríi rẹ̀.Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀runmo sì kó àwọn agbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta

13. Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi:Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.Òun yóò tún ìlú mi kọ́yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

14. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì,àti àwọn Ṣábíáṣì—wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹwọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn;kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

15. Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Ísírẹ́lì

16. Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tìwọn yóò sì kan àbùkù;gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

17. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni a ó gbàlà láti ọwọ́ OlúwaPẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójú tì yín,títí ayé àìnípẹ̀kun.

18. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí—ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,Òun ni Ọlọ́run;ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,Òun ló ṣe é;Òun kò dá a láti wà lófo,ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀—Òun wí pé:“Èmi ni Olúwa,kò sì sí ẹlòmìíràn.

19. Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó farasin,láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn;Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jákọ́bù pé‘Ẹ wá mi lórí asán.’Èmi Olúwa sọ òtítọ́;Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.

20. “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìṣáǹṣá láti àwọnọrílẹ̀ èdè wá.Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.

21. Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wájẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;kò sí ẹlòmìíràn àfi èmi.

Ka pipe ipin Àìsáyà 45