Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 35:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Àti opópónà kan yóò wà níbẹ̀:a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà-Mímọ́.Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náààwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.

9. Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lóríi rẹ̀;a kì yóò rí wọn níbẹ̀.Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,

10. àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin;ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 35