Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 35:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Aṣálẹ̀ àti ìyàngbẹ ilẹ̀ ni inú rẹ̀ yóò dùn;ihà yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.Gẹ́gẹ́ bí ewéko kúrókúsì,

2. òun yóò bẹ́ná jáde;yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kígbe fún ayọ̀.Ògo Lẹ́bánónì ni a ó fi fún un,ọlá ńlá Kámẹ́lì àti Ṣárónì;wọn yóò rí ògo Olúwa,àti ọlá ńlá Ọlọ́run wa.

3. Fún ọwọ́ àìlera lókun,mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:

4. Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;Ọlọ́run yín yóò wá,òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan;pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan mímọ́òun yóò wá láti gbà yín là.”

5. Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́júàti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.

6. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.Odò yóò tú jáde nínú ihààti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.

7. Yanrìn tí ń jóná yóò di adágúnilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.Òpópó ibi tí àwọn ajáko sùn tẹ́lẹ̀ríkoríko àti koríko odò àti ewéko mìíràn yóò hù níbẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 35