Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 30:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsi, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”

22. Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

23. Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú.

24. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.

25. Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.

26. Òṣùpá yóò sì tàn bí òòrùn, àti ìtànsán òòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27. Kíyèsí i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wápẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùruèéfín tí ó nípọn;ètè rẹ̀ kún fún ìbínúahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.

Ka pipe ipin Àìsáyà 30