Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 29:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yaàwọn ènìyàn yìí lẹ́nupẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”

15. Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbunláti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùntí wọ́n sì rò pé,“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”

16. Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé“Òun kọ́ ló ṣe mí”?Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,“kò mọ nǹkan”?

17. Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́a kò ní sọ Lẹ́bánónì di pápá ẹlẹ́tù lójúàti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí ihà?

18. Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,láti inú fìrífìrí àti òkùnkùnni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

19. Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

20. Aláìláàánú yóò pòórá,àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò dàwátì,gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—

21. àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní kóòtùtí ẹ fi ẹ̀rí èkè dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Ábúráhámù padà sọ sí ilé Jákọ́bù:“Ojú kì yóò ti Jákọ́bù mọ́;ojúu wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 29