Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 29:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún ọ, Áríẹ́lì, Áríẹ́lì,ìlú níbi tí Dáfídì tẹ̀dó sí!Fi ọdún kún ọdúnsì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀ṣíwájú.

2. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èmi yóò dó ti Áríẹ́lìòun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sunkún,òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.

3. Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;Èmi yóò sì fi ilé-ìṣọ́ yí ọ ká:èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdótini mi dojú kọ ọ́.

4. Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti iwin láti ilẹ̀ wá,láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹyóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

5. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.Lójijì, ní ìṣẹ́jú àáyá,

6. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wápẹ̀lú àrá, ilẹ̀ ríri àti ariwo ńláàti ẹ̀fúúfù líle àti iná ajónirunorílẹ̀ èdè tí ó bá Áríẹ́lì jà,tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódì rẹ̀tí ó sì dó tì í,yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,bí ìran ní òru

7. Lẹ́yìn náà,ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo

8. àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá péòun ń jẹun,ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀;àti bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá péòun ń mumi,ṣùgbọ́n nígbà tí ó yajú pẹ́ ẹ́, pẹ̀lú òùngbẹtí kò dáwọ́ dúró ni.Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdètí ń bá òkè Ṣíhónì jà.

9. Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,ẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n kì í se ti ọtí bíà.

10. Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sóríi yín:ó ti dì yín lójú (ẹ̀yin wòlíì);ó ti bo oríi yín (ẹ̀yin aríran).

Ka pipe ipin Àìsáyà 29