Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 28:8-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo orí i tábìlì ni ó kún fún èébìkò sì sí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

9. “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìhìn in rẹ̀ fún?Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú un wọn,sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

10. Nítorí tí í ṣe:Ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹdíẹ̀ níhìnín, díẹ̀ lọ́hùn ún.”

11. Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí ṣọ̀rọ̀

12. àwọn tí ó sọ fún wí pé,“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tísílẹ̀.

13. Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di péṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ;díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀húnbẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn,wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùna ó sì gbá wọn mú.

14. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,tí ń jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jérúsálẹ́mù.

15. Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,kò le kàn wá lára,nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o waàti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa.”

16. Fún ìdí náà èyí ni ohun tí Olúwa Jèhófà sọ:“Kíyèsíì, mo gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Ṣíhónìòkúta tí a dánwò,òkúta igunlé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájúẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀le kì yóò ní ìfòyà.

17. Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀nàti òdòdó òjé òṣùwọ̀n;yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tíẹ ń farapamọ́ sí mọ́lẹ̀.

18. Májẹ̀muu yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fagi lé;àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

19. Nígbàkúùgbà tí ó bá ti wá niyóò máa gbé ọ lọ,ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”Ìmòye ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yìíyóò máa mú ìpayà ńlá wá.

20. Ibùsùn kúrújù fún ìnara lé lórí,ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.

21. Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení òkè Péráṣímùyóò ru ara rẹ̀ ṣókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení àfonífojì Gíbíónì—láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.

22. Ní ìsinsìn yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; Olúwa, àní Olúwa àwọn-ogun ti sọ fún minípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

23. Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.

24. Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìnyóò ha máa tulẹ̀ títí títí ni?Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kíó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

Ka pipe ipin Àìsáyà 28