Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 28:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀,òun a sì mì ín.

5. Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,Òdòdó tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

6. Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́àti oríṣun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padàní ẹnubodè.

7. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí wáìnìwọ́n pòòrì dànìn fún ọtí bíà,Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí bíàwọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnìwọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí bíà,wọ́n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

8. Gbogbo orí i tábìlì ni ó kún fún èébìkò sì sí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

9. “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìhìn in rẹ̀ fún?Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú un wọn,sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

10. Nítorí tí í ṣe:Ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹdíẹ̀ níhìnín, díẹ̀ lọ́hùn ún.”

11. Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí ṣọ̀rọ̀

12. àwọn tí ó sọ fún wí pé,“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tísílẹ̀.

13. Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di péṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ;díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀húnbẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn,wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùna ó sì gbá wọn mú.

14. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,tí ń jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jérúsálẹ́mù.

15. Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,kò le kàn wá lára,nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o waàti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 28