Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 2:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Àìsáyà ọmọ Ámósì rínípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù:

2. Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́òkè tẹ́ḿpìlì Olúwani a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kékeré lọ,gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì máa ṣàn sínú un rẹ̀.

3. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn ó si sọ pé“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè lọsí òkè Olúwa,sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù.Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”Òfin yóò jáde láti Síhónì wá,àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jérúsálẹ́mù wá.

4. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn orílẹ̀ èdèyóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.Orílẹ̀ èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀ èdè mọ́,bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

5. Wá, ẹ̀yìn ará ilée Jákọ́bùẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.Ọjọ́ Olúwa.

6. Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,ìwọ ilé Jákọ́bù.Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ó ti ìlà oòrùn wá,wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Fílístínìwọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà

7. Ilẹ̀ wọ́n kún fún fàdákà àti wúràìṣúra wọn kò sì ní òpin.Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.

8. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ọwọ́ ara wọn,èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tikálára wọn ti ṣe.

9. Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,má ṣe dáríjìn wọ́n.

10. Wọ inú àpáta lọ,fi ara pamọ́ nínú èrùpẹkúrò nínú ìpayà Olúwa,àti ògo ọlá ńlá rẹ̀!

11. Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.

12. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan nípamọ́fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíganítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀sílẹ̀),

13. nítorí gbogbo igi kedari Lẹ́bánónì, tó ga tó rìpóàti gbogbo óákù Báṣánì,

14. nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńláàti àwọn òkè kéé kèè kéé,

15. fún ilé ìṣọ́ gíga gígaàti àwọn odi ìdáàbòbò,

Ka pipe ipin Àìsáyà 2