Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 17:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì,tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kùsórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7. Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójúsókè sí Ẹlẹ́dàá wọnwọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

8. Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn,wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9. Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10. Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín;ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín.

11. Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àsàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hú jáde,àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́nẹ mú kí wọ́n rúdí,ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìkóórè kò ní mú nǹkan wání ọjọ́ àrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

12. Kíyèsii, ìrunú àwọn orílẹ̀ èdè—wọ́n ń runú bí ìgbì òkun!Kíyèsii, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyànwọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń búramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré,a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

14. Ní ihà, ìpayà òjijì!Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.

Ka pipe ipin Àìsáyà 17