Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 17:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jákọ́bù yóò ṣá;ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

5. Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkóórè kó àwọnirúgbìn tí ó dúró jọtí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Réfémù.

6. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì,tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kùsórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7. Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójúsókè sí Ẹlẹ́dàá wọnwọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

8. Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn,wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9. Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10. Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín;ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín.

Ka pipe ipin Àìsáyà 17