Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 10:10-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ.

11. Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀?

12. Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.

13. Nítorí ó sọ pé:“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyíàti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò,Mo sì ti kó ìṣúra wọn.Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

14. Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè.Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdèkò sí èyí tí ó fapálupá,tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15. Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,tàbí kí ayùn fọnnu sí ẹni tí ó ń lò ó?Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

16. Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sóríàwọn akíkanjú jagunjagun,lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọgẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

17. Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì yóò di iná,ẹni Mímọ́ an wọn ahọ́n iná,ní ijọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì runàti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

18. Gbogbo ẹwà igbóo rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràágbogbo rẹ̀ ni yóò run pátapáta,gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó sàìṣàn ti í ṣòfò dànù.

19. Àwọn igi tí yóò kù nínú igbóo rẹ̀yóò kéré níye,tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

20. Ní ijọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lìÀwọn tí ó yè ní ilée Jákọ́bùkò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náàtí ó lùwọ́n bolẹ̀ṣùgbọ́n yóò gbẹ́kẹ̀lé OlúwaẸni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

21. Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jákọ́bùyóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn an rẹ, ìwọ Ísírẹ́lìdàbí yanrìn ní òkun,ẹni díẹ̀ ni yóò padà.A ti pàṣẹ ìparunà kún wọ́ sílẹ̀ àti òdodo.

23. Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú-un ṣẹ,ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórígbogbo ilẹ̀ náà.

24. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Ṣíhónì,Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Ásíríà,tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tìyín bíÉjíbítì ti ṣe.

25. Láìpẹ́, ìbínú mi síi yín yóò wá sí òpinn ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,fún ìparun wọn.”

26. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Mídíánìní òkè Órébù,yóò sì gbé ọ̀páa rẹ̀ lé orí omigẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Éjíbítì.

27. Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrùu wọn kúrò ní èjìká a yín,àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yína ó fọ́ àjàgà náà,nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

28. Wọ́n wọ Áíyátì,Wọ́n gba Mígírónì kọjáWọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mísímásì.

29. Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,“Àwa ó tẹ̀dó sí Gébà lóru yìí.”Rámà mì tìtìGíbíà ti Ṣọ́ọ̀lù sá lọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 10