Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 1:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹtí ẹ yà ṣọ́tọ̀ni ọkàn mi kórìíra.Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n.

15. Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà,Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,Èmi kò ni tẹ́ti sí i.Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

16. Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

17. kọ́ láti ṣe rere!Wá ìdájọ́ òtítọ́,tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,gbà ẹjọ́ opó rò.

18. “Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,”ni Olúwa wí.“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,wọn ó sì funfun bí i yìnyín,bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.

19. Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.

20. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,idà ni a ó fi pa yín run.”Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

21. Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ ríṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!

22. Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là.

Ka pipe ipin Àìsáyà 1