Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 15:15-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ rẹ̀ ti murá.”

16. Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa sọ́ ilé.

17. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.

18. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí ìwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kérétì, àti gbogbo àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ará Gítì, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gátì wá, sì kọjá níwájú ọba.

19. Ọba sì wí fún Ítaì, ará Gítì pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé aléjò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀.

20. Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ kákiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

21. Ítaì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láàyè, àti bí Olúwa mi ọba ti ń bẹ láàyè, nítòótọ́ níbikíbi tí Olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbáà ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”

22. Dáfídì sì wí fún Ítaì pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ítaì ará Gítì náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kékèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sunkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá odò Kídírónì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.

24. Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.

25. Ọba sì wí fún Sádókù pé, “Sì tún gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú: bí èmi bá rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí-ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nì yìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti tọ́ ní ojú rẹ̀.”

27. Ọba sì wí fún Sádókù àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Áhímásì ọmọ rẹ, àti Jónátanì ọmọ Ábíátárì.

28. Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.”

29. Sádókù àti Ábíátarì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jérúsálẹ́mù: wọ́n sì gbé ibẹ̀.

30. Dáfídì sì ń gòkè lọ ní òkè igi ólífì, o sì ń sunkun bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹṣẹ̀: gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.

31. Ẹnìkan sì sọ fún Dáfídì pé, “Áhítófélì wà nínú àwọn asọ̀tẹ̀ pẹ̀lù Ábúsálómù.” Dáfídì sì wí pé, “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Áhítófélì di asán.”

32. Ó sì ṣe, Dáfídì dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Húsáì ará Áríkà sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀.

33. Dáfídì sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 15