Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 24:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.

10. Ní àkókò náà àwọn ìjòyè Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sílẹ̀ Jérúsálẹ́mù wọ́n sì gbé dófì kalẹ̀ fún un,

11. Nebukadinéṣárì fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìjòyè fi ogun dótì í.

12. Jéhóíákímù ọba Júdà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Bábílónì ó mú Jéhóíákínì ẹlẹ́wọ̀n.

13. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadinéṣárì kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì

14. Ti kọ́ fún Olúwa, Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.

15. Nebukadinéṣárì mú Jéhóíákínì ní ìgbékùn lọ sí Bábílónì. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ile náà.

16. Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn (1000) oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ.

17. Ó sì mú Mátanáyà arákùnrin baba Jéhóíákínì, ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ṣedekáyà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 24