Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 2:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà tí wọ́n rékọjá, Èlíjà sì wí fún Èlíṣà pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10. “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Èlíjà wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹsin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Èlíjà sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà.

12. Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì!” Èlíṣà kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13. Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jọ́dánì.

14. Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà?” Ó bèèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá.

15. Àwọn ọmọ wòlíì láti Jẹ́ríkò, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Èlíjà simi lé Èlíṣà.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀.

16. “Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”“Rárá,” Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17. Ṣùgbọ́n wọ́n forítì í títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò ríi.

18. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

Ka pipe ipin 2 Ọba 2