Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 19:23-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹÌwọ ti ṣe ìkójọpọ̀ èébú sí Olúwa.Ìwọ sì ti sọ pé,“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ miÈmi sì ti fi dé orí àwọn òkè ńlá,ibi gíga jùlọ ní LébánónìMo sì ti gé igi gíga jùlọ kédárìlulẹ̀, àti àyò igi fírì rẹ̀.Mo ti dé ibi orí òkè ìbùwọ́ ẹ̀gbẹ́ kanibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ.

24. Mo ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìMo sì mu omi níbẹ̀.Pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi,Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Éjíbítì.”

25. “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjápé ìwọ ti yí ìlú olódi padà díòkítì àlàpà òkúta.

26. Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,wọ́n ti dàá láàmúwọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú.Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá,gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè,gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.

27. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọdúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbílọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ: sí mi.

28. Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi,Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imúrẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ,èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ’

29. “Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà:“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀.

30. Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Júdàyóò sì tún hu gbòǹgbòlábẹ́, yóò sì so èṣo lókè.

31. Láti inú Jérúsálẹ́mù ní àwọn ìyókù yóò ti wáàti láti orí òkè Ṣíónì ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣá àsálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí.

32. “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa ṣọ nípa ti ọba Áṣíríà:“Kò ní wọ ìlú yìítàbí ta ọfà síbí.Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lúàpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.

33. Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá niyóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,ni Olúwa wí.

34. Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí,èmi yóò sì paámọ́ fún èmi tìkálára mi àti fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”

35. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Aṣíríà. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!

36. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Nínéfè ó sì dúró níbẹ̀.

37. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nísírókù, ọmọkùnrin rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣárésérì gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Árárátì Ésáráhádónì ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 19