Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 19:12-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gósánì, Háránì Réṣéfù àti gbogbo ènìyàn Édẹ́nì tí wọ́n wà ní Télásárì?

13. Níbo ni ọba Hámátì wa, ọba Árípádì, ọba ìlú Séfárífáímù, ti Hénà, tàbí ti Ífà gbé wà?”

14. Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú Olúwa.

15. Heṣekáyà gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.

16. Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú ù rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.

17. “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn.

18. Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe Olúwa. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.

19. Nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkanṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”

20. Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà.

21. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“ ‘Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíónìkẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.

22. Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?Lórí ta ni ìwọ ti gbé gbé ohùn rẹsókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?Lórí ẹni mímọ́ ti Ísírẹ́lì!

23. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹÌwọ ti ṣe ìkójọpọ̀ èébú sí Olúwa.Ìwọ sì ti sọ pé,“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ miÈmi sì ti fi dé orí àwọn òkè ńlá,ibi gíga jùlọ ní LébánónìMo sì ti gé igi gíga jùlọ kédárìlulẹ̀, àti àyò igi fírì rẹ̀.Mo ti dé ibi orí òkè ìbùwọ́ ẹ̀gbẹ́ kanibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ.

24. Mo ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìMo sì mu omi níbẹ̀.Pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi,Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Éjíbítì.”

25. “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjápé ìwọ ti yí ìlú olódi padà díòkítì àlàpà òkúta.

26. Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,wọ́n ti dàá láàmúwọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú.Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá,gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè,gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.

27. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọdúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbílọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ: sí mi.

28. Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi,Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imúrẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ,èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ’

29. “Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà:“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 19