Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 18:28-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Nígbà náà aláṣẹ dìdé ó sì pè jáde ní èdè Hébérù pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásìría!

29. Èyí ni ohun tí ọba sọ: má ṣe jẹ́ kí Héṣékíáyà tàn ọ́ jẹ kò le gbà ọ́ kúrò ní ọwọ́ mi

30. Má se jẹ́ kí Héṣékíáyà tì ọ́ láti gbàgbọ́ nínú Olúwa nípa sísọ pé, ‘Olúwa yóò gbà wá nítòótọ́; ìlú yìí ni wọn kò ní fi lé ọba ìlú Ásíríà lọ́wọ́.’

31. “Má ṣe tẹ́tí sí Héṣékíáyà. Èyí ni ohun tí ọba Ásíríà sọ: ‘Ṣe àlàáfíà pẹ̀lú mi kí o sì jáde wá sí ọ̀dọ̀ sí mi.’ Nígbà náà olúkúlùkù yín yóò jẹun láti inú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́, yóò sì mumi láti inú àmù rẹ̀,

32. Títí tí èmi yóò fi wá mú ọ lọ sí ilé gẹ́gẹ́ bí i tìrẹ, ilẹ̀ ọkà àti ọtí wáìnì, ilẹ̀ ouńjẹ àti ọgbà àjàrà, ilẹ̀ òróró ólífì àti ti ilẹ̀ oyin; yàn ìye má sì ṣe yàn ikú!“Kí ẹ má ṣe gbọ́ tí Heṣekáyà, nítorí ó ń tàn yín tí ó ba tí wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá?’

33. Ṣé òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè kankan ti gba ilé rẹ lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà?

34. Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Árípádì gbé wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣérárifáímù, Hẹ́nà àti ífà gbé wà? Wọ́n ha gba Ṣámáríà kúrò lọ́wọ́ mi bí?

35. Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”

36. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, “Ẹ má ṣe dáa lóhùn.”

37. Nígbà náà Élíákímù ọmọ Hílíkíyà olùtọ́jú ààfin, Séríbù akọ̀wé àti Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ránsẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Héṣékíáyà, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdárí pápá ti sọ.

Ka pipe ipin 2 Ọba 18