Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 16:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹtàdínlógún Pẹ́kà ọmọ Remálíà, Áhásì ọmọ Jótamù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ síi jọba.

2. Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ó sì jọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jérúsálẹ́mù, kò si ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísíráẹ́lì, nítòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ ó kọjá láàrin iná, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ ìrírà àwọn aláìkọlà, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísíráẹ́lì.

4. Ó sì rúbọ, ó sì ṣun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5. Nígbà náà ni Résínì ọba Ṣíríà àti Pẹ́kà ọmọ Rèmálíà ọba Ísíráẹ́lì gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù láti jagun: wọ́n dó ti Áhásì, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.

6. Ní àkókò náà, Résínì Ọba Ṣíríà gba Élátì padà fún Ṣíríà, ó sì lé àwọn ènìyàn Júdà kúrò ní Élátì: àwọn ará Ṣíríà sì wá sí Élíátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

7. Áhásì sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tigilati-Pílésérì ọba Ásíríà wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Síríà, àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí ó díde sí mi.”

8. Áhásì sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúrà ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Ásíríà ní ọrẹ.

9. Ọba Ásíríà sì gbọ́ tirẹ̀: nítórí ọba Ásíríà gòkè wá sí Dámásíkù, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbékùn lọ sí Kírì, ó sì pa Résínì.

10. Ọba sì lọ sí Dámásíkù láti pàdé Tigilati-Pílésérì, ọba Ásíríà, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Dámásíkù: Áhásì ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Úráyà àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.

11. Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù; bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù.

12. Nígbà tí ọba sì ti Dámásíkù dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rúbọ lórí rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 16