Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 13:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹtàlélógún ti Jóásì ọmọ ọba Áhásáyà ti Júdà, Jéhóáhásì ọmọ Jéhù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tadínlógún.

2. Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn.

3. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hásáélì ọba Ṣíríà àti Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀.

4. Nígbà náà Jéhóáhásì kígbe ó wá ojú rere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Ṣíríà ti ń ni Ísírẹ́lì lára gidigidi.

5. Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Ísírẹ́lì, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Ṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.

6. Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú nínú rẹ̀ pẹ̀lú òpó Áṣérà dúró síbẹ̀ ní Ṣamáríà.

7. Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ ogun Jéhóáhásì àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, nítorí ọba Ṣíríà ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.

8. Fún ti ìyókù ìṣe Jéhóáhásì fún ìgbà, tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

9. Jéhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samáríà, Jéhóásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

10. Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jóásì ọba Júdà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ó sì jọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

11. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì èyí tí ó ti ti Ísírẹ́lì láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

12. Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jéhóásì fún ìgbà tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

13. Jéhóásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jéróbóámù sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jéhóásì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Ọba 13