Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 12:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.

11. Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.

12. Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún titun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹ́ḿpílì ṣe.

13. Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, àlùmágàjí fìtílà, àwokòtò, ipè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

14. A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

15. Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà sírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé.

16. Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa: ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.

17. Ní déédéé àkókò yìí, Hásáélì ọba Ṣíríà gòkè lọ láti dojúkọ Gátì àti láti fi agbára mú un. Nígbà náà, ó yípadà láti dójukọ Jérúsálẹ́mù.

18. Ṣùgbọ́n Jóásì ọba Júdà mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jéhósáfátì, Jéhórámù àti Áhásáyà, àwọn ọba Júdà, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkálára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hásáélì; ọba Ṣíríà, tí ó sì fa padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

19. Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Jóásì, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

20. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Bẹti-Mílò ní ọ̀nà sí Ṣílà.

21. Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Jósábádì ọmọ Ṣíméátì àti Jéhósábádì ọmọ Ṣómérì. Ó kú, wọ́n sì sin-ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Ọba 12