Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 29:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.

3. Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.

4. Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.

5. Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́.

6. Àwọn baba wa jẹ́ aláìsòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.

7. Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa Fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Ísirẹ́lì.

8. Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìyanu àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.

9. Ìdí nìyí tí àwọn bàbá wa ṣe ṣubú nípa idà àti idí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa ti wọn kó wọ́n ní ìgbékùn.

10. Nísinsìn yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.

11. Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsìn yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”

12. Nígbà náà àwọn ọmọ Léfì wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́:nínú àwọn ọmọ Kóhátì,Máhátì ọmọ Ámásà: àti jóẹ́lì ọmọ Ásáríyà;nínú àwọn ọmọ Mérárì,Kíṣì ọmọ Ábídì àti Ásáríyà ọmọ Jéháiéíèlì;nínú àwọn ọmọ Gésónì,Jóà, ọmọ símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà;

13. nínú àwọn ọmọ Élisáfánì,Ṣímírì àti Jégíèlì;nínú àwọn ọmọ Ásáfù,Sékáríà àti Mátaníyà;

14. nínú àwọn ọmọ Hémánì,Jéhíélì àti Ṣíméhì;nínú àwọn ọmọ Jédútùnì,Ṣémáíà àti Húsíélì.

15. Nigbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ile Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti paáláṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 29