Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 25:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù.

8. Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ subú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Olúwa ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”

9. Ámásíà sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùnún tálẹ́ntì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́-ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́?”Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni Ámásíà, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Éfíráimù ká. Ó sì rán wọn lọ lé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì padà lọlé pẹ̀lu ìbínú ńlá.

11. Ámásíà nígbà náà, tó agbára rẹ̀ ó sì fọ̀nàhan àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Séírì.

12. Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.

13. Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.

14. Nígbà tí Ámásíà padà ní ibi pípa àwọn ará Édómù, ó mú àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn Séírì padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn Ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rúbọ fún wọn.

15. Ìbínú Olúwa ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 25