Nígbà tí Ámásíà padà ní ibi pípa àwọn ará Édómù, ó mú àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn Séírì padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn Ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rúbọ fún wọn.