Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 25:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ámásíà nígbà náà, tó agbára rẹ̀ ó sì fọ̀nàhan àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Séírì.

12. Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.

13. Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.

14. Nígbà tí Ámásíà padà ní ibi pípa àwọn ará Édómù, ó mú àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn Séírì padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn Ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rúbọ fún wọn.

15. Ìbínú Olúwa ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”

16. Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgbà ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?”Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tísí ìmọ̀ràn mi”

17. Lẹ́yìn tí Ámásíà ọba Júdà ti bèèrè lọ́wọ́ àwọn olùgbà á lámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehóáṣì ọmọ Jehóáháṣì ọmọ Jéhù, ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá bá mi lóju kojú.”

18. Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.

19. Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 25