Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 25:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ámásíà jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóadánì, ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

2. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn.

3. Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn onísẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba.

4. Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mósè, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé: “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn; Olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

5. Ámásíà, pe gbogbo àwọn ènìyàn Júdà pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọrọrún fún gbogbo Júdà àti Bẹńjámínì, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì ríi pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.

6. Ó sì yá (100,000) ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Ísírẹ́lì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá àwọn talẹ́ntì fàdákà.

7. Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù.

8. Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ subú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Olúwa ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”

9. Ámásíà sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùnún tálẹ́ntì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́-ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́?”Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni Ámásíà, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Éfíráimù ká. Ó sì rán wọn lọ lé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì padà lọlé pẹ̀lu ìbínú ńlá.

11. Ámásíà nígbà náà, tó agbára rẹ̀ ó sì fọ̀nàhan àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Séírì.

12. Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.

13. Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 25