Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 20:16-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ní ọla, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú ibi ṣíṣe wa, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú ihà Jérúẹ́lì.

17. Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní àyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”

18. Jóhóṣáfátì tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa.

19. Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ọmọ Kóhátì àti àwọn kórì sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.

20. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí ihà Tékòa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jéhóṣáfátì dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹgbọ́ mi, Júdà àti ènìyàn Jérúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ ninú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.”

21. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé:“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé.”

22. Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ́yìn sí àwọn ọkùnrín Ámónì àti Móábù àti òkè Séírì tí ó ń gbógun ti Júdà, wọ́n sì kọlù wọ́n.

23. Àwọn ọkùnrin Ámónì àti Móábu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Séírì láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin làti òkè Séírì, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.

24. Nígbà tí Àwọn èníyàn Júdà jáde sí ìhà ilé ìsọ́ ní ihà, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí àyè sá.

25. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.

26. Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27. Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.

28. Wọ́n sì wọ Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin àti dùùrù àti ipè.

29. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀ta Ísírẹ́lì jà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 20